Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 144: Ó Tún Ń Bọ̀ Lẹ́ẹ̀kan Sí I

He's Coming Once Again

Ó tún ń bọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i
Fún 'dàndé èèyàn Rẹ;
K' àwọn mímọ́ le wà n' n' ògo,
Níbi tí Òun gbé wà
Gb' orí t' á a tẹ̀ bà rò,
W' òkè, yọ̀, k' ó kọrin;
Ó ń bọ̀ nínú ọlá nlá Rẹ,
Ọba wa ológo

Ayé yìí yóò bẹ̀rù,
Ọ̀run yóò sì fò lọ;
Níbo l' èèyàn ibi yóò wà
L' ọjọ́ t' ó tóbi yìí?
Kò s' ibi ìsádí
Tàb' aàbò lọ́wọ́ 'jì;
Ọjọ́ ẹ̀san sú ní sánmọ̀
Ọjọ́ àánú kọjá.

Ìtànsán ojú Rẹ
Yóò p' àwọn búburú;
Kò s' ẹni t' yóò le pé oòkọ
Jésù pẹ̀lú ẹ̀gàn.
Kò ní sí 'kòrírà.
F' àwọn atẹ̀lé Rẹ
Ìjàfara alágbára
Yóò pa á l' ẹkún n' jọ́ náà