Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 140: Ọba T' Ó Ń Bọ̀ Sún M' Ẹtílé

The Coming King Is At The Door

Ọba t' ó ń bọ̀ sún m' ẹtílé
Ẹn' t' ó rù àgbélébù wa;
Àwọn olódodo nìkan,
Ni Òun yóò kó lọ 'lé.

Ẹtílé, ẹtílé,
Ẹtílé, àn' Ó sún m' ẹtílé
Ó ń bọ̀ wa. Ó ń bọ̀ wa,
Àn' Ó sún mọ́ ẹtílé.

Àmì t' ó ń fi bíbọ̀ Rẹ hàn,
Ń ṣe láti ọdún dé ọdún;
Láìpẹ́ a ó rí oòrọ̀ ayọ̀,
Ọjọ́ aìkú t' ọ̀run.

Ẹtílé, ẹtílé,
Ẹtílé, àn' Ó sún m' ẹtílé
Ó ń bọ̀ wa. Ó ń bọ̀ wa,
Àn' Ó sún mọ́ ẹtílé.

Má ṣe wá 'sìmí t' ayé yìí,
Má ṣe w' àlàáfíà t' ìhín;
Títí Olùgbàlà yóò fi dé,
Láti pa 'nà ẹ̀ṣẹ̀.

Ẹtílé, ẹtílé,
Ẹtílé, àn' Ó sún m' ẹtílé
Ó ń bọ̀ wa. Ó ń bọ̀ wa,
Àn' Ó sún mọ́ ẹtílé.

'Gbà náà ni ayé títun náà,
Tí a ó máa gbé títí láéláé,
Ara wa yóò d' ara aìkú,
Ìgbà kì yóò d' òpin.

Ẹtílé, ẹtílé,
Ẹtílé, àn' Ó sún m' ẹtílé
Ó ń bọ̀ wa. Ó ń bọ̀ wa,
Àn' Ó sún mọ́ ẹtílé.