Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 138: A Kò Mọ̀ 'Gbà T' Olúwa Yóò Dé
We Know Not The Time When He Cometh
A kò mọ̀ 'gbà t' Olúwa yóò dé
L' ọ̀sán, l' órù tàbí l' àáàrọ̀,
Ó le jẹ́ ní àfẹ́mójúmọ́,
Ó sì le jẹ́ ní akúkọ,
Ó pàṣẹ fún wa k' á máa ṣọ́nà,
Kí 'mọ́lẹ̀ wa má ṣe sòókùn,
Kí Ó le rí wa 'gbàt' Ó bá dé
Pé a ń dúró, a sì ń ṣọ́nà.
A ń dúró dé Ọ,
A wà sì ń ṣọ́nà,
A ń dúrà dé Ọ,
A ń dúró, a ń ṣọ́nà fún Ọ.
Mo rò nípa ìfẹ́ 'yànu Rẹ,
Àti ìràpadà nlá Rẹ;
Ó fi 'búgbé ògo Rẹ sílẹ̀;
Láti kú fún àwọn t' ó nù.
Mo gbàgbọ́ pé yóò tẹ Ọ́ lọ́run
Nígbà tí àwọn tó Ọ kú fún
Bá ń yọ ní ìrètí bíbọ̀ Rẹ
Ní dídúró àt' ìṣọ́nà.
A ń dúró dé Ọ,
A wà sì ń ṣọ́nà,
A ń dúrà dé Ọ,
A ń dúró, a ń ṣọ́nà fún Ọ.
A! Jésù Olùràpadà mi,
Ìwọ mọ̀ pé mo fi 'rètí
Dúró láti le rí ògo Rẹ
K' Ìwọ le kí mi kú àbò,
B' Ó ó bá yọ s' ọ̀pọ̀ b' Onídàjọ́,
Tí wọn sì ń sá níwájú Rẹ,
Èmi yóò padé Rẹ bí Ọ̀rẹ́,
Mo dúró mo ń ṣọ́nà fún Ọ.
A ń dúró dé Ọ,
A wà sì ń ṣọ́nà,
A ń dúrà dé Ọ,
A ń dúró, a ń ṣọ́nà fún Ọ.