Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 137: Jésù Ìjọ Tó Ọ Ràpadà Ń Jí
Lord Thy Ransomed Church is Waking
Jésù ìjọ tó Ọ ràpadà
Ń jí l' oj' oòrùn n' bi gbogbo,
Ó mọ̀ pé ọjọ́ náà ń bọ̀ wa
Tí Oko-'yàwó y' óò dé,
Ó ń jí láti gbà iṣúra
T' Ó f' ẹ̀jẹ̀ owón Rẹ rà:
Àti láti ní gbẹ́kẹ̀lé
S' ohun tí ikú Rẹ ṣe.
A yìn Ọ f' ọjọ́ rere yìí,
Fún ẹ̀wọ̀ àrọ̀kúrò;
Pé, níp' agbára Ẹ̀mí Rẹ
Ìwọ tún mú wa sọjí;
A yìn Ọ fún 'hìnrere Rẹ
T' ó ń lọ sí gbogbo ayé;
A yìn Ọ, 'tór' ìfẹ́ Bàbá
Ń lọ déédé ní ọwọ́ Rẹ.
A yìn Ọ f' àwọn t' á gbàlà
Tí ń ṣ' àájò àwọn t' ó nù
Láti kọ 'rín ayọ̀ náà.
A yìn Ọ f' àwọn aláìsàn
T' ó wá 'dọ̀ Rẹ fú 'wòsàn;
Àti f' àwọn oníìgbàgbọ́
Tí ń j' àǹfààní ìfẹ́ Rẹ.
Fi ìfẹ́ oòkọ Rẹ owón
Mú ìtara wa gbóná,
Títí gbogb' orílẹ̀-èdè
Yóò kédé ìgbàlà Rẹ
Jẹ́ k' á máa rètí bíbọ̀ Rẹ
K' á ṣọ́nà títí Ó ó fi dé,
Nígbà t' á a bá sì múra tán,
Olúwa mú wa rẹ 'lé.