Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 136: Wò Ó! Ó Ń Bọ̀ Pẹ̀l' Àwọ̀sánmọ̀

Lo! He Comes With Clouds Descending

Wò ó! Ó ń bọ̀
Pẹ̀l' àwọ̀sánmọ̀,
Ẹni t' á a pà f' ẹlẹ́ṣẹ̀;
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Mímọ́
Ń y' ayọ̀ 'ṣẹ́gun lẹ́yìn Rẹ
Alelú-yà! Ale-lú-yà!
Ale-lú-yà!
Ọlọ́run ń bọ̀ wá jobà.

Gbogb' ojú ni yóò rí I wáyí,
Nín' aṣọ ògo t' Ó wọ;
Àwọn t' ó gàn Án, àwọn t' ó ta Á
T' ó kàn Án mọ́ àgbélébù,
Yóò bú s' ẹkún, yóò bú s' ẹkún,
'Gbà wọn bá rí Mesaya.

'Gbàt' ìpè 'kẹyìn bá ti dún,
Ọ̀run àt' ayé yóò sá;
Gbogb' àwọn t' ó kòrírà Rẹ
Yóò gbọ́ ìpè ọjọ́ náà
Wá s' ìdájọ́! Wá s' ìdájọ́!
Wá s' ìdájọ́! Wá máa bọ̀!

Bẹ́ẹ̀ ni, Amín! k' á jubà Rẹ,
L' or' ìtẹ́ Rẹ aìlópin;
Olùgbàlà, gbà agbára,
Ògo àt' ìjọba Rẹ;
Wá nísiyí! Wá nísiyí!
Gbà 'jọba náà f' ara Rẹ!