Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 134: Ó Hà Le Jẹ́ Pé Mo R' Ojú Rere Ẹ̀jẹ̀ Olùgbàlà?
And Can It be
Ó hà le jẹ́ pé mo r' ojú
Rere ẹ̀jẹ̀ Olùgbàlà?
Ó kú f' èmi t' Ó fà 'yà Rẹ,
F' èmi t' Ó lé E s' ẹnu ikú?
Oore-ọ̀fẹ́! Ó hà le jẹ́
Pé Ọlọ́run mi kú fún mi?
Oore-ọ̀fẹ́! Ó hà le jẹ́
Pé Ọlọ́run mi kú fún mi?
Ó f' ìtẹ́ Bàbá Rẹ sílẹ̀,
Oore Rẹ, ọ̀fẹ́ ni, ó kún;
Ó bò gbogb' ọlá Rẹ sílẹ̀,
Ó t' ẹ̀jẹ̀ Rẹ sílẹ̀ fún wa,
Iṣẹ́ àánú l' Ó ṣe fún wa,
Ọlọ́run mi, Ó wá mi rí.
Oore-ọ̀fẹ́! Ó hà le jẹ́
Pé Ọlọ́run mi kú fún mi?
Ọkàn mi wà nínú ìdè,
Ẹ̀ṣẹ̀ àt' òkùnkùn dúú-dúú?
Ojú Rẹ mú 'wòsàn jáde,
Mo jí, 'mọ́lẹ̀ Rẹ yí mi ká;
Ẹ̀wọ̀n mi jà, mo d' ọm' ìnira,
Mo dìde, mo sì ń tẹ̀ lé Ọ.
Oore-ọ̀fẹ́! Ó hà le jẹ́
Pé Ọlọ́run mi kú fún mi?
Èmi kò bẹ̀rù ẹ̀bí mọ́,
T' èmi ní agbára Jésù:
Ẹlẹ́dàá mi sọ mí d' àáyè,
Ó d' aṣọ ododo bò mi;
Mo wá 'dí 'tẹ́ pẹ̀lú 'gboyà;
Mo ẹ̀b' adé l' ọwọ́ Kríst' mi.
Oore-ọ̀fẹ́! Ó hà le jẹ́
Pé Ọlọ́run mi kú fún mi?