Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 133: Sọ Ìtàn 'Gbàaní Fún Mi

Tell me the Old, Old Story

Sọ ìtàn 'gbàaní fún mi,
T' ohun àárí l' òkè;
Ti Jésù àt' ògo Rẹ,
Jésù òun ìfẹ́ Rẹ:
F' àpẹ̀lẹ̀ sọ ìtàn náà,
Gẹ́gẹ́ bí s' ọmọdé;
'Torí mo ṣ' aláìlòkun,
Mo tún jẹ́ aláìyé.

Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Ti Jésù àt' ìfẹ́ Rẹ.

F' àpẹ̀lẹ̀ sọ ìtàn náà
Sọ ó k' ó yé ni dáadáa
Rántí p' èmi l' ẹlẹ́ṣẹ̀,
Tí Jésù wá gbàlà;
Máa rán ìtàn náà fún mi,
Bí ìwọ yóò bá jẹ́
Ọ̀rẹ́ ìtùnú fún mi,
L' àkókò ìdààmú.

Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Ti Jésù àt' ìfẹ́ Rẹ.

Tún ìtàn náà sọ fún mi,
Bí ẹ̀rù bá ń bà ọ,
P' ẹwà àt' ògo ayé yìí
Ń lọ mi l' ọ̀nà ayé;
Nígbà t' ọ̀rọ̀ ayé bá
Ń fẹ́ ojú rẹ mọ́ mi,
Sọ ìtàn ìgbà ní fún mi,
"Jésù Krístì gbà ọ là."

Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Sọ ìtàn 'gbà ní fún mi
Ti Jésù àt' ìfẹ́ Rẹ.