Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 130: Kríst' Wà Láàyè! Kristẹ́n Kọrin
Christ is Alive, Let Christians Sing
Kríst' wà láàyè! Kristẹ́n kọrin
Kò sí l' or' àgbélébùú mọ́,
Kí t' ẹ̀rù t' ọmọ kún f' orin,
Ìfẹ́ Rẹ fún wa kò ní sá.
Kríst' wà láàyè! Ó le wà ní
Ibi gbogbo nígbà gbogbo;
Ó wá gbà àkóso ayé,
Ó wá ṣẹ́gun ohun gbogbo.
N' nú ẹ̀gàn ọ̀tẹ̀ àt' ogun,
Tí àwọ̀, èdè ń dá sílẹ̀;
A ń dá Krísti l' ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n
Ìfẹ́ Rẹ sí wa kò pẹ́ din.
Kríst' wà láàyè ọba aìkú
Ó jobà l' or' ayé t' Ó dá;
Títí ẹ̀dá gbogbo yóò fi
Mọ̀ bí ìfẹ́ Rẹ ti pọ̀ tó!