Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 129: Jésù Fẹ́ Mi, Mo Mọ̀ Bẹ́ẹ̀

Jesus Loves Me, This I know

Jésù fẹ́ mi, mo mọ̀ bẹ́ẹ̀,
Bibeli l' ó sọ fún mi;
Tìrẹ l' àwọn ọmọdé,
Wọn kò l' agbára, Òun ni.

A! Jésù fẹ́ mi!
A! Jésù fẹ́ mi!
A! Jésù fẹ́ mi!
Bibẹ́l' sọ fún mi bẹ́ẹ̀.

Jésù fẹ́ mi, Ẹn' t' ó kú
Láti ṣí ọ̀run sílẹ̀;
Òun yóò wẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù:
Yóò jẹ́ k' ọmọ Rẹ wọ 'lé.

A! Jésù fẹ́ mi!
A! Jésù fẹ́ mi!
A! Jésù fẹ́ mi!
Bibẹ́l' sọ fún mi bẹ́ẹ̀.

Jésù, jọ̀ọ́ gbà ọkàn mi
Yà á sí mímọ́ f' ara Rẹ
L' or' àgbélébùú lo kú
Èm' ó wà láàyè fún Ọ.

A! Jésù fẹ́ mi!
A! Jésù fẹ́ mi!
A! Jésù fẹ́ mi!
Bibẹ́l' sọ fún mi bẹ́ẹ̀.