Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 127: Jésù L' Ohun Gbogbo Fún Mi
Jesus Is All The World To Me
Jésù l' ohun gbogbo fún mi,
Ayọ̀ àt' ìyè mi,
Agbára mi lójoojúmọ́,
Láìsí Rẹ n ó ṣubú,
Nínú 'bànújẹ́ mo tọ Ọ́ lọ,
Kò s' ẹni le mú 'nú mi dùn,
N' nú 'bànújẹ́, Ó dùn mi n' nú
Ọ̀rẹ́ mi ni.
Jésù l' ohun gbogbo fún mi,
Ọ̀rẹ́ nígbà 'dánwò,
Mo tọ Ọ́ lọ fún ìbùkún
Ó sì ń fi wọn fún mi,
Ó ń rán oòrùn àti òjò,
Ó sì ń pèsè 'kórè oko,
Oòrùn, òjò àti ire;
Ọ̀rẹ́ mi ni
Jésù l' ohun gbogbo fún mi,
N ó jẹ́ olóòótọ́ sí I;
A! n ó ti ṣe sọ Ọ̀rẹ́ yìí
'Gbàt' ó ń ṣ' òótọ́ sí mi?
Ní títẹ̀ lé E n kò ṣako mọ́,
Ó sì ń sọ mí t' ọ̀sán t' órù,
Gbà mo ń tẹ̀ lé E, t' ọ̀sán t' órù
Ọ̀rẹ́ mi ni
Jésù l' ohun gbogbo fún mi,
Kò s' ọ̀rẹ́ mìíràn mọ́;
Mo gbẹ́kẹ̀lé E nísisìyí,
Títí d' òpin ayé;
Ìgbé-ayé rere pẹ̀lú,
Ọ̀rẹ́ t' ó fẹ́ràn mi báyìí,
Ìyè pẹ̀lú ayọ̀ títí,
Ọ̀rẹ́ mi ni.