Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 126: Òjò Ìbùkún Yóò Sì Rọ̀
There Shall Be Showers Of Blessing
Òjò ìbùkún yóò o sì rọ̀;
Èyí n' ìlérí ìfẹ́;
Àkókò ìtùrà yóò dé
Lát' ọ̀dọ̀ Olùgbàlà.
Òjò Ìbùkún,
Òjò ìbùkún l' á ń fẹ́;
Ìrì àánú ń ṣe yí wa ká
Ṣùgbọ́n òjò l' á ń tọrọ.
Òjò ìbùkún yóò sì rọ̀;
Ohun gbogbo yóò sọjí,
Lórí òkè òun pẹ̀tẹ́lẹ̀
Ìró ọ̀pọ̀ òjò ń bọ̀.
Òjò Ìbùkún,
Òjò ìbùkún l' á ń fẹ́;
Ìrì àánú ń ṣe yí wa ká
Ṣùgbọ́n òjò l' á ń tọrọ.
Òjò ìbùkún yóò sì rọ̀;
Rán wọn sí wa Olúwa!
Fún wa n' ìtùrà nísiyí,
Wá, b' ọlá fún ọ̀rọ̀ Rẹ.
Òjò Ìbùkún,
Òjò ìbùkún l' á ń fẹ́;
Ìrì àánú ń ṣe yí wa ká
Ṣùgbọ́n òjò l' á ń tọrọ.
Òjò ìbùkún yóò sì rọ̀
Ìbá jẹ́ le rọ̀ lóníì,
B' á ti ń jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run,
Tí a sì ń ké pé Jésù.
Òjò Ìbùkún,
Òjò ìbùkún l' á ń fẹ́;
Ìrì àánú ń ṣe yí wa ká
Ṣùgbọ́n òjò l' á ń tọrọ.