Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 125: Ìwọ Sọ̀rọ̀, Ènìyàn Gbọ́

Thy Voice Hath Spoken

Ìwọ sọ̀rọ̀, ènìyàn gbọ́,
A ti f' ìfẹ́ 'yànu Rẹ hàn,
Ǹjẹ́ ní wákàtí yìí
Mú k' ọfà ọ̀rọ̀ Rẹ f' òye
Ẹ̀ṣẹ̀ àt' ododo àti
Agbára nlá Rẹ hàn.

'Wọ m' aṣọ ìbòjú kúrò;
Ẹ̀ṣẹ̀ 'kọ̀kọ̀ t' á ń gbé pamọ́
L' ó hàn sí Ọ gbangba,
Jésù, m' ọkàn ìyèméjì
Yàgò f' ẹ̀ṣẹ̀ àt' ọ̀nà 'bi,
K' oní jẹ́ ọjọ́ nlá.

Ṣẹ́gun ọ̀tá kí òun má bàá
Máa mú wọn ní ìgbèkùn lọ
Àwọn t' á f' ẹ̀jẹ̀ rà,
Jẹ́ k' àwọn t' ẹ̀ṣẹ̀ ń dá láàmú.
Tí kò sí le bò láìsí Rẹ
Le n' ìgbàlà kíkún.

Jà ẹ̀wọ̀n òun ṣèkèṣèkè,
Fún elégbo ní ìwòsàn,
Sì tú oùndé sílẹ̀;
Fọ 'kàn t' ẹ̀ṣẹ̀ ti bàjẹ́ mọ́
Ṣe é l' olóòótọ́ lát' ọkàn wa,
N' ìfẹ́ òun 'wà mímọ́.

Jésù sọ̀r' agbára Rẹ pé,
"Èmi ó mú 'yọnú rẹ lọ,"
Sì mú láàlàá wa tán,
K' ọkàn t' ó bá f' ara fún Ọ,
Lát' oní lọ le d' elérìí,
Tó l' àlàáfíà Rẹ.