Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 123: Mo L' Ọ̀rẹ́ Kan
I've Found a Friend
Mo l' Ọ̀rẹ́ kan, ìfẹ́ Rẹ pọ̀,
Ó fẹ́ mi k' èmi t' ó mọ̀ Ọ́n
Ọ̀kùn ìfẹ́ l' ó fi fà mí,
Ó sì dé mi mọ́ 'ra Rẹ,
Kòkó 'fẹ́ Rẹ, t' á á kò le tú,
Lo mọ́ ọkàn mi síbẹ̀,
Mo jẹ́ Tìrẹ, Òun jẹ́ tèmi,
Láé àti títí láéláé.
Mo l' Ọ̀rẹ́ kan, ìfẹ́ Rẹ pọ̀,
Ó kú láti gbà mí là,
Ìyè nìkan kò l' Ó fún mi,
Ó fi ara Rẹ jí mi
N kò ní p' ohun kan ní tèmi,
N ó pa á mọ́ f' Olùfúnni;
Ọkàn, agbára, ẹ̀mí mi,
Tìrẹ ni títí láéláé.
Mo l' Ọ̀rẹ́ kan, ìfẹ́ Rẹ pọ̀,
Gbogb' agbára l' á fi fún Un,
K' Ó le sọ mí ní ajò mi,
K' Ó sì mú mi dé ọ̀run,
Ògo aìlópin ń tàn 'mọ́lẹ̀
Láti fún mi ní òkun;
N ó ṣọ́ra n ó ṣiṣẹ́, n ó jà
Lẹ́yìn náà, n ó sìmí láé.
Mo l' Ọ̀rẹ́ kan, ìfẹ́ Rẹ pọ̀,
Oníyọ̀nú, Olóòótọ́,
Olùgbìmọ̀, àt' Amọ̀nà,
Aláàbò t' ó l' agbára,
Kín ni 'bá le yà mí lọ́dọ̀
Ẹni fẹ́ mi pọ̀ tó yìí?
Ìyè, ikú, ayé, 'bòjì?
Bẹ́ẹ̀ kọ́! Mo jẹ́ Tìrẹ láé.