Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 121: N' Ó Kọrin Ìfẹ́ Jésù

I Will Sing of Jesus' Love

N ó kọrin ìfẹ́ Jésù,
Kọrin Ẹn' t' ó kọ́ fẹ́ mi;
Tór' Ó fi ọ̀run sílẹ̀,
Ó kú l' orí Kalfari.

N ó kọrin ìfẹ́ Jésù
Ìyìn aìkú l' èm' ó fún Un;
'Tór' Ó kú k' èm' le yè,
N ó kọrin 'fẹ́ Rẹ sí mi.

Ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ Jésù,
T' ayé àt' ọ̀run kò mọ̀,
B' ẹ̀ṣẹ̀ mi dúdú kìrìkìrì,
Ó le wẹ̀ ẹ́ funfun bí snò.

N ó kọrin ìfẹ́ Jésù
Ìyìn aìkú l' èm' ó fún Un;
'Tór' Ó kú k' èm' le yè,
N ó kọrin 'fẹ́ Rẹ sí mi.

Kò s' iṣẹ́ 'rẹ l' ọwọ́ mi,
Òun ha ti ṣe fẹ́ràn mi,
'Wọ ti ṣẹ́gun ọkàn mi,
Jẹ́ kí n le f' ìfẹ́ mi hàn.

N ó kọrin ìfẹ́ Jésù
Ìyìn aìkú l' èm' ó fún Un;
'Tór' Ó kú k' èm' le yè,
N ó kọrin 'fẹ́ Rẹ sí mi.