Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 12: Dìde Ẹ̀mí Mi, Ndé
Arise My Soul, Arise
Dìde ẹ̀mí mi, ndé
Gbọ́n ẹ̀rù ẹ̀bi rẹ;
Ẹni tá a pa fún mi
Fara hàn n' torí mi:
Mo l' Onígbòwò n' ìdìí 'tẹ́;
A kọ 'rúkọ mi s' ọwọ́ Rẹ.
Ó ń bẹ l' òkè láéláé
Láti bẹ̀bẹ̀ fún mi,
Ó ń f' ìfẹ́ 'ra padà
Àt' ẹ̀jẹ̀ Rẹ bẹ̀bẹ̀;
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ṣe ẹ̀ẹ́tù gbogb' ayé,
Ó ń búù, wọn ìtẹ́ or'-ọ̀fẹ́.
Ọgbẹ́ márùn-ún l' Ó gbà
Ní òkè Kálfárì;
Wọ́n ń gbàdúr' àìtàṣẹ
Wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ n' torí mi
Wọ́n ń kè, Dàríjì, dàríjì.
Máà jẹ́ k' ẹlẹ́ṣẹ̀ náà k' ó kú
Bàbá gb' ẹ̀bẹ̀ Ẹni
Àmì òróró Rẹ;
Kò lè kọ àdúrà
Ti Ọmọ Rẹ ọ̀wọ́n;
Ẹ̀mí Rẹ ń dáhùn ẹ̀bẹ̀ náà,
Pé, mo d' àtúnbí Ọlọ́run.