Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 119: L' Òwúrọ̀ Ọjọ́ Àjíǹdé
On The Resurrection Morning
L' òwúrọ̀ Ọjọ́ Àjíǹdé,
T' ara t' ọkàn yóò padé,
Ẹkún, 'kàaánú òun ìróra
Yóò d' òpin.
Níhìn-ín wọn kò le ṣàì-pínya,
Kí ara bá le sìnmí,
K' ó sì fi ìdákẹ̀ rọ̀rọ̀
Sùn fonfon.
Fún 'gbà díẹ̀ ara àárẹ̀ yìí
L' á gbé s' ibi 'sìmí rẹ̀;
Títí di ìmọ́lẹ̀ oòrọ̀
Àjíǹdé.
Ọkàn t' ó kàaánú ní 'siyí,
T' ó sì ń gbàdúrà kíkan,
Yóò bú s' orin ayọ̀ l' ọjọ́
Àjíǹdé.
Ara àt' ọkàn yóò dàpọ̀,
Ìpínya kò ní sí mọ́;
Wọn ó jí l' àwòrán Kríst' ni
'Tẹ́lọ̀run.
A! ẹwà náà àt' ayé náà
Yóò ti pọ̀ tó l' Àjíǹdé!
Yóò dúró, b' ọ̀run àt' ayé
Bá fò lọ.
L' oòrọ̀ ọjọ́ àjíǹdé wa,
'Bòjì yóò m' okú rẹ̀ wá;
Bàbá, ìyá, ọmọ, ara
Yóò padé.
Sí 'dàpọ̀ tí ó dùn báyìí
Jésù má ṣàì kà wá yé;
N' nú 'yà àt' ayọ̀, kàrò
M' Àgbélébù.