Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 118: Jésù Yè; Títí Ayé

Jesus Lives; Thy Terror Now

Jésù yè; títí ayé
Ẹ̀rù ikú kò bà ní mọ́;
Jésù yè, Nítorí náà
Ìṣà okú kò n' ipa mọ́,
Alelúyà!

Jésù yè; lát' oní lọ,
Ikú jẹ́ ọ̀nà sí ìyè;
Èyí yóò jẹ́ 'tùnú wa,
'Gbàt' àkókò ikú bá dé
Alelúyà!

Jésù yè; fún wa l' ó kú,
Ǹjẹ́ Tìrẹ ni a ó máa ṣe
A ó f' ọkàn funfun sìn Ín
A ó f' ògo f' Olùgbàlà.
Alelúyà!

Jésù yè; èyí dájú,
Ikú àt' ipa òkùnkùn
Kì yóò le yà ní kúrò
Nínú ìfẹ́ ńlá ti Jésù.
Alelúyà!

Jésù yè; gbogbo 'jọba
L' ọ̀run, ní ayé di Tìrẹ;
Ẹ jẹ́ kí a máa tẹ̀lé E,
Kí a le jobà pẹ̀lú Rẹ,
Alelúyà!