Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 116: Ìjà D' Òpin
The Strife is O'er
Alelúyà, Alelúyà, Alelúyà!
Ìjà d' òpin, ogun parí;
Olùgbàlà ti ṣẹ́gun ná,
Orin ìyìn ni a ó máa kọ "Alelúyà!"
Ikú ti ṣa gbogbo 'pa rẹ̀
Ṣùgbọ́n Krístì tú ọ̀tá ká;
Jẹ́ k' á máa hó ihó ayọ̀
"Alelúyà!"
Ọjọ́ mẹ́ta ẹ̀dùn kọjá
Ó jìndé kúrò n' nú okú;
Ògo f' Olùràpadà wa!
"Alelúyà!"
Olúwa, nípa iná Rẹ,
L' Ó d' àwọn 'ránṣẹ́ Rẹ sílẹ̀,
K' á wà láàyè, k' á máa yìn Ọ
"Alelúyà!"