Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 114: Máa G' Ẹṣin Lọ Nín' Ọlá Rẹ
Ride On Ride On In Majesty
Máa g' ẹṣin lọ nín' ọlá Rẹ!
Gbọ́, gbogb' ẹ̀yà ń ké Hosana,
Olùgbàlà, máa lọ jẹ̀jẹ̀,
Pẹ̀lú 'mọ ọ̀pẹ àt' aṣọ.
Máa g' ẹṣin lọ nín' ọlá Rẹ!
G' ẹṣin lọ kú pẹ̀lú 'rẹ̀lè;
Krístì, ìṣẹ́gun Rẹ bẹ̀rẹ̀
Lórí ikú, àti ẹ̀ṣẹ̀.
Máa g' ẹṣin lọ nín' ọlá Rẹ!
Àwọn áńgẹ́lì l' ók' ọ̀run
Ń wò 'lẹ̀ pẹ̀l' ẹ̀dùn òun 'yànu
Láti r' ẹbọ t' ó sún mọ́lẹ̀
Máa g' ẹṣin lọ nín' ọlá Rẹ.
G' ẹṣin lọ kú pẹ̀lú 'rẹ̀lè;
F' ara dà 'róra òun ikú,
Gb' agbára Rẹ, kó O sì jobà.