Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 112: N' Ìbòjì L' Ó Sùn Sí, Kríst' Olùgbàlà

Low in the Grave He Lays

N' ìbòjì l' Ó sùn sí,
Kríst' Olùgbàlà;
Dúró d' ọjọ́ tí ń bọ̀,
Olúwa mi.'

Ó jìndé nínú 'bòjì
Pẹ̀lú 'ṣẹ́gun l' orí ọ̀tá Rẹ;
Ó jìndé b' aṣẹ́gun ipa òkùnkùn
Ó sì wà láéláé pẹ̀lú àwọn mímọ́
Ó jìndé, Ó jìndé,
Alelúyà, Kríst' jìndé.

L' àṣán wọn sọ bòjì,
Kríst' Olùgbàlà;
L' àṣán l' á f' èédì dí i,
Olúwa mi.

Ó jìndé nínú 'bòjì
Pẹ̀lú 'ṣẹ́gun l' orí ọ̀tá Rẹ;
Ó jìndé b' aṣẹ́gun ipa òkùnkùn
Ó sì wà láéláé pẹ̀lú àwọn mímọ́
Ó jìndé, Ó jìndé,
Alelúyà, Kríst' jìndé.

Ikú kò n' ipa mọ́
Kríst' Olùgbàlà;
Ó ti ṣẹ́gun ikú
Olúwa mi.

Ó jìndé nínú 'bòjì
Pẹ̀lú 'ṣẹ́gun l' orí ọ̀tá Rẹ;
Ó jìndé b' aṣẹ́gun ipa òkùnkùn
Ó sì wà láéláé pẹ̀lú àwọn mímọ́
Ó jìndé, Ó jìndé,
Alelúyà, Kríst' jìndé.