Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 110: 'Gbà Tí Mo Ń Wò Àgbélébù
When I Survey the Wondrous Cross
'Gbà tí mo ń wò àgbélébù
Tí a kàn Ọba ògo mọ́;
Mo kà gbogbo ọrọ̀ s' òfò,
Mo kẹ́gàn gbogbo ògo mi.
Wò ó b' ẹ̀dùn pẹ̀lú 'fẹ́ tí ń ṣàn
Lát' orí, ọwọ́, ẹsẹ̀ Rẹ:
Ìfẹ́ dàpọ̀ m' ẹ̀dùn bẹ́ẹ̀ rí,
A f' ẹ̀gún ṣ' adé ògo rí?
Gbà tí èmi ẹni ẹgbẹ́
Rí dàríjì gbà l' ọ̀dọ̀ Rẹ
K' á má ṣe gbọ́ pé mo ń halẹ̀
B' ó yẹ 'nú àgbélébù Rẹ.
Gbogbo ayé bá jẹ́ tèmi,
Kò tó oore tí ń bá mú wá;
Ìfẹ́ 'yànu t' ó pọ̀ tó 'yìí,
Yẹ k' ó gbà gbogbo ẹ̀mí mi.