Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 108: Ó Ṣé! Jésù Ta 'Jẹ̀ Rẹ 'Lẹ̀?
Alas! and Did My Saviour Bleed?
Ó ṣé! Jésù ta 'jẹ̀ Rẹ 'lẹ̀?
Ọba mi hà kú bí?
Ó hà le f' orí mímọ́ Rẹ
F' ẹlẹ́ṣẹ̀ bí èmi?
Níbi àgbélébù ni mo kọ́ r' ìmọ́lẹ̀
Níbẹ̀, ẹ̀rù ọkàn mi sì fò lọ;
Níbẹ̀, n' pa ìgbàgbọ́ mo tún ríran,
Báyìí mo d' aláyọ̀ 'n' gbogb' ọjọ́.
Òun hà jẹ 'róra l' or' igi
Fún ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ṣe?
Àánú àt' oòr'-ọ̀fẹ́ 'yànu!
Àt' ìfẹ́ t' ó jìnlẹ̀.
Níbi àgbélébù ni mo kọ́ r' ìmọ́lẹ̀
Níbẹ̀, ẹ̀rù ọkàn mi sì fò lọ;
Níbẹ̀, n' pa ìgbàgbọ́ mo tún ríran,
Báyìí mo d' aláyọ̀ 'n' gbogb' ọjọ́.
Ṣùgbọ́n ẹ̀dùn kò le san an tán,
Gbèsè 'fẹ́ tí mo jẹ;
Jésù mo f' ara mi sílẹ̀,
Èyí ni mo le ṣe.
Níbi àgbélébù ni mo kọ́ r' ìmọ́lẹ̀
Níbẹ̀, ẹ̀rù ọkàn mi sì fò lọ;
Níbẹ̀, n' pa ìgbàgbọ́ mo tún ríran,
Báyìí mo d' aláyọ̀ 'n' gbogb' ọjọ́.