Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 106: L' or' Òkè Lẹ́yìn 'Lú
On a Hill Far Away
L' or' òkè lẹ́yìn 'lú
l' àgbélébù kan wà,
Àpẹẹrẹ ìyà àt' ẹ̀gàn,
Ọkàn mi fà síbẹ̀,
'b' Olùfẹ́ mi owón
T' á a pà f' ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ayé.
Mo gbé àgbélébù Rẹ náà rù,
Títí n ó fi kó ère mi jọ
Mo rọ̀ mọ́ àgbélébù mi náà,
K' èmi le dé adé níkẹyìn.
A! àgbélébù yìí
T' ọmọráyé kẹ́gàn,
L' ó l' ẹwà púpọ̀ l' ojú mi,
Nítór' Ọm' Ọlọ́run
bò ògo Rẹ sílẹ̀,
Ó gb' ẹ̀ṣẹ̀ mi gun Kalfari.
Mo gbé àgbélébù Rẹ náà rù,
Títí n ó fi kó ère mi jọ
Mo rọ̀ mọ́ àgbélébù mi náà,
K' èmi le dé adé níkẹyìn.
S' Ẹni t' ó kú fún mi,
èmi yóò j' olóòótọ́
N ó yọ s' ẹ̀gàn àt' ìtìjú,
Nígbòṣe yóò pè mí,
lọ 'lé ayérayé
Kí n sì le pín nín' ògo Rẹ.
Mo gbé àgbélébù Rẹ náà rù,
Títí n ó fi kó ère mi jọ
Mo rọ̀ mọ́ àgbélébù mi náà,
K' èmi le dé adé níkẹyìn.