Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 105: Ẹni 'Kàaánú! Orúkọ
Man of Sorrows
Ẹni 'kàaánú! -- orúkọ
T' á ń pè Ọmọ Ọlọ́run
T' ó wá gbà ẹlẹ́ṣẹ̀ là!
Alelúyà! Olùgbàlà!
Ó faradà eléyà
A dá A l' ẹ̀bí n' ipò mi;
Ẹ̀jẹ̀ Rẹ ṣẹ̀ẹ̀tú fún mi:
Alelúyà! Olùgbàlà!
Òtọ̀ṣ' ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wa:
Aláìlábàwọ́n ni Òun
Ǹjẹ́ lóòótọ́ l' Ó ṣẹ̀tùtù?
Alelúyà! Olùgbàlà!
A gbé E kó s' orí igi,
Ó ké pé, Ó ti parí!
A gbé E ga l' ọ̀run n' ísiyí
Alelúyà! Olùgbàlà!
'Gbàt' Ọba Ògo bá dé,
Láti m' ẹni Rẹ rẹ 'lé,
A ó kọrin yìí l' ọ̀tún
Alelúyà! Olùgbàlà!