Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 104: Ẹ Lọ Sí Getsemane
Go to Dark Gethsemane
Ẹ lọ sí Getsemane,
"Ẹ̀yin tí Èṣù ń dánwò;"
Wò 'pọ́njú Olùgbàlà;
Ẹ bá A ṣ' ọ̀nà n' gbà 'dánwò;
Ronú nípa ẹ̀dùn Rẹ;
Kọ àdú'à lọ́dọ̀ Jésù.
Wò Ó nínú gbàngàn 'dájọ́
Wò Ó bí Ó ti ń fara dà
Iná ìdè òun ẹ̀gàn;
Ìfẹ́ wa kún ọkàn Rẹ;
Má sá fún 'yà òun tìjú;
Kọ n' pa àgbélébù Kríst'.
F' ẹ̀dùn gòkè Kálífárì;
Lọ wolé ní àṣẹ Rẹ,
Ṣàkíyèsí àkókò
T' ìrúb' Ọlọ́run parí
Ó kígbe pé, 'Ó parí,
Kọ n' pa 'kú lọ́dọ̀ Jésù.