Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 103: Jésù Ṣamọ̀n' Èrò Mi
Prince of Peace, Control My Will
Jésù ṣamọ̀n' èrò mi,
Jẹ́ k' ọkàn mi dúró jẹ́ẹ́;
M' ẹ̀rù òun 'yèméjì lọ,
M' àlàáfíà w' ọkàn mi.
'Wọ ti f' ẹ̀jẹ̀ Rẹ rà mí,
Ó sì 'kún ọ̀run sílẹ̀;
N' ìdàpọ̀ pẹ̀lú Jésù
L' àlàáfíà jẹ́ t' èmi.
Ìfẹ́ Tìrẹ ni k' á ṣe
K' ìfẹ́ wa jumọ̀ sọ̀kan;
L' ẹ̀rù òun 'yèméjì lọ,
F' àlàáfíà Rẹ fún mi.