Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 102: Sọ Ìtàn Ti Jésù Fún Mi
Tell Me the Story of Jesus
Sọ ìtàn, ti Jésù fún mi,
Kọ ọ̀rọ̀ náà s' ayà mi;
Sọ ìtàn 'yebíye fún mi,
T' ó dùn jù yìí t' á ti ń gbọ́.
Sọ b' àwọn áńgẹ́lì l' ọ̀run
Ti ń f' orin kí ìbí Rẹ,
Ògo ni f' Ọlọ́run l' òkè,
Àlàáfíà f' ayé yìí.
Sọ ìtàn ti Jésù fún mi,
Kọ ọ̀rọ̀ náà s' ayà mi,
Sọ ìtàn 'yebíye fún mi,
T' ó dùn jù yìí t' á ti ń gbọ́.
Òun nìkan gbà'wẹ̀ nín' ọgbà,
Sọ b' Ó ti lo ayé Rẹ,
B' á ti ń dán An wò tór' ẹ̀ṣẹ̀ wa,
T' Ó sì ṣẹ́gun níkẹyìn,
Sọ nípa ọdún iṣẹ́ Rẹ,
Sọ nípa 'bànújẹ́ Rẹ,
A kẹ́gàn Rẹ, a pọ́n-ọn lójú,
Ó d' Ẹni ìkọ̀sílẹ̀.
Sọ ìtàn ti Jésù fún mi,
Kọ ọ̀rọ̀ náà s' ayà mi,
Sọ ìtàn 'yebíye fún mi,
T' ó dùn jù yìí t' á ti ń gbọ́.
Sọ t' àgbélébù t' á kàn Án mọ́,
T' Ó f' ìkẹ́dùn nlá jọrọ,
Sọ nípa 'bòjì t' á á tẹ́ E sí,
Sọ nípa t' àjíǹde Rẹ;
Ìfẹ́ l' ó borí ìtàn náà,
Ó sì hàn gbangba níbẹ̀;
N ó sọkún b' ó ti ń wí jẹ̀jẹ̀.
Ìfẹ́ ti rà mí padà.
Sọ ìtàn ti Jésù fún mi,
Kọ ọ̀rọ̀ náà s' ayà mi,
Sọ ìtàn 'yebíye fún mi,
T' ó dùn jù yìí t' á ti ń gbọ́.