Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)
Orin 100: N' Ó Kọrin Ìtàn Ìyànu Ti Krístì
I will Sing the Wondrous Story
N' ó kọrin ìtàn ìyànu
Ti Krístì t' Ó kú fún mi;
Ó f' ilé ògo Rẹ sílẹ̀,
Ó kú l' òkè Kálífárì,
N' ó kọrin ìtàn ìyànu
Ti Krístì t' Ó kú fún mi.
N' ó kọ pẹ̀l' àwọn ológo
Lẹ́bà òkun dídàn náà.
Mo nù; ṣùgbọ́n Jésù wá mi
Ó w' àgùtàn t' ó nù rí;
Ó f' ọwọ́ 'fẹ́ gbà mí mọ́ra,
Ó mú mi wá s' ọ̀nà Rẹ.
N' ó kọrin ìtàn ìyànu
Ti Krístì t' Ó kú fún mi.
N' ó kọ pẹ̀l' àwọn ológo
Lẹ́bà òkun dídàn náà.
Mo gb' ọgbẹ́; Jésù wò mí sàn
Mo ṣubú; Ó gbé mi rò;
Mo f' ojú, ìfòyà mú mi
Ó sọ mí d' òmìnira.
N' ó kọrin ìtàn ìyànu
Ti Krístì t' Ó kú fún mi.
N' ó kọ pẹ̀l' àwọn ológo
Lẹ́bà òkun dídàn náà.
Oòkùn ayé bò mí mọ́lẹ̀
'Bànújẹ́ kún ọ̀nà mi;
Ṣùgbọ́n Jésù wà pẹ̀lú mi
Ó ń sìn mi lọ láìs' ewu.
N' ó kọrin ìtàn ìyànu
Ti Krístì t' Ó kú fún mi.
N' ó kọ pẹ̀l' àwọn ológo
Lẹ́bà òkun dídàn náà.