Ìwé Orin Mímọ́ (Yoruba SDA Hymnal)

Orin 10: Yìn Olúwa! Ó Tọ́, Ó Yẹ

Praise Ye The Lord

Yìn Olúwa! ó tọ́, ó yẹ
K' a f' ọkàn àt' ohùn wa yìn In;
Ìwà àt' iṣẹ́ Rẹ pe wá
K' a f' ayọ̀ kọrin ìyìn Rẹ.

Ó dá 'ràwọ̀ s' ojú-sánmà,
Ó sọ gbogbo wọn l' orúkọ;
Ọgbọ́n Rẹ ẹnìkan kò mọ̀ ọn
Ó jìnlẹ̀ jù èrò wa lọ.

Kọrin s' Olúwa; ẹ gbé E ga
Ẹni tà kùukùu sí sánmà,
T' Ó rán ojò sórí ilẹ̀,
Tí kò jẹ́ kí ó rọ̀ láṣán.

Ó fi oko s' òkè lọ́ṣọ́ọ̀,
Ó m' ọkà hù nínú oko;
Ó fi oúnjẹ fún ẹranko
Àti àwọn ọmọ ìwò.

Ìjọ Rẹ l' ẹ́wà l' ọ́jú Rẹ,
Inú Rẹ dùn s' àwọn 'mọ Rẹ;
Ó mọ̀ 'rètí àt' ẹ̀rù wọn,
Ó fẹ́ àwọn t' ó dàbí Rẹ.